Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Léfítíkù 23:1-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Olúwa sọ fún Mósè wí pé,

2. “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí o sì wí fún wọn pé, ‘Ìwọ̀nyí ni àwọn àjọ̀dún tí mo ti yàn, àwọn àjọ̀dún ti Olúwa èyí tí ẹ gbọdọ̀ kéde gẹ́gẹ́ bí ìpàdé àjọ mímọ́.

3. “ ‘Ọjọ́ mẹ́fà ni ẹ le fi ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ọjọ́ keje ni ọjọ́ ìsinmi. Ọjọ́ ìpàdé àjọ mímọ́. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan, níbikíbi tí ẹ bá ń gbé. Ọjọ́ ìsinmi Olúwa ni.

4. “ ‘Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọdún tí Olúwa yàn, ìpàdé àjọ mímọ́ tí ẹ gbọdọ̀ kéde lákókò wọn.

5. Àjọ ìrékọjá Olúwa bẹ̀rẹ̀ ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìn-ín-ní (Épírì).

6. Ní ọjọ́ kẹẹ̀dógún oṣù kìnm-ín-ní ni àjọ̀dún àkàrà àìwú (àkàrà tí kò ní ìwúkàrà) tí Olúwa bẹ̀rẹ̀ fún ọjọ́ méje ni ẹ gbọdọ̀ fi jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà.

7. Ẹ pe ìpàdé àjọ mímọ́ ní ọjọ́ kìn-ín-ní, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ ojúmọ́ yín.

8. Ọjọ́ méje ni kí ẹ fi mú ọrẹ tí a fi iná ṣe wá fún Olúwa. Ní ọjọ́ keje, ẹ pe ìpàdé àjọ mímọ́, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ ojúmọ́.’ ”

9. Olúwa sọ fún Mósè pe

10. “Sọ fún àwọn ará Ísírẹ́lì, kí o sì wí fún wọn pé, ‘Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí èmi yóò fún yín, tí ẹ bá ń ṣe ìkórè, kí ẹ mú síírì ọkà àkọ́kọ́ tí ẹ kórè wá fún àlùfáà.

11. Kí o fí síírì ọkà náà níwájú Olúwa, kí ó le jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún yín: kí àlùfáà fì í ní ọjọ́ kejì ìsinmi.

12. Ní ọjọ́ tí ẹ bá fí síírì ọkà náà, kí ẹ mú ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dúnkan láìní àbùkù rú ẹbọ sísun sí Olúwa.

13. Pẹ̀lú ọrẹ ọkà rẹ tí ó jẹ́ ìdá méjì nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n ẹ́fà (èyí jẹ́ lítà mẹ́rin ààbọ̀) ti ìyẹ̀fun, tí a fi òróró pò ọrẹ tí a fi iná ṣe fún Olúwa òórùn dídùn pẹ̀lú ọrẹ ohun mímu rẹ̀ tí í ṣe ìdámẹ́rin òsùwọ̀n hini (Èyí jẹ́ lítà kan).

14. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ àkàrà kankan tàbí kí ẹ sun ọkà tuntun títí di ọjọ́ tí ẹ fi mú ọrẹ yín wá fún Ọlọ́run yín. Èyí ni ìlànà ayérayé fún ìran tí ń bọ̀, níbikíbi tí ẹ bá ń gbé.

15. “ ‘Ẹ ka ọ̀sẹ̀ méje gbangba, láti ọjọ́ kejì ọjọ́ ìsinmi, àní ọjọ́ tí ẹ mú sììrì ọkà fífì wá.

Ka pipe ipin Léfítíkù 23