Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Léfítíkù 22:9-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. “ ‘Kí àwọn àlùfáà pa ìlànà mi mọ́, kí wọn má baà jẹ̀bi, kí wọn sì kú nítorí pé wọ́n ṣe ọrẹ wọ̀nyí pẹ̀lú fífojútẹ́ḿbẹ́lú wọn. Èmi ni Olúwa tí ó sọ wọ́n di mímọ́.

10. “ ‘Kò sí ẹnikẹ́ni lẹ́yìn ìdílé àlùfáà tí ó le jẹ ọrẹ mímọ́ náà, bẹ́ẹ̀ ni, àlejò àlùfáà tàbí alágbàṣe rẹ̀ kò le jẹ ẹ́.

11. Ṣùgbọ́n bí àlùfáà bá ra ẹrú, pẹ̀lú owó, tàbí tí a bí ẹrú kan nínú ìdílé rẹ̀, ẹrú náà lè jẹ oúnjẹ rẹ̀.

12. Bí ọmọbìnrin àlùfáà bá fẹ́ ẹni tí kì í ṣe àlùfáà, kò gbọdọ̀ jẹ nínú èyíkéyi nínú ohun ọrẹ mímọ́.

13. Ṣùgbọ́n bí ọmọbìnrin àlùfáà bá jẹ́ opó tàbí tí a ti kọ ọ́ sílẹ̀, ṣùgbọ́n tí kò lọ́mọ tí ó sì padà sínú ilé bàbá rẹ̀ láti máa gbé bẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìgbà èwe rẹ̀, ó le jẹ oúnjẹ bàbá rẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, ẹnikẹ́ni tí kò lẹtọ (láṣẹ) kò gbọdọ̀ jẹ èyíkéyí nínú oúnjẹ náà.

14. “ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá ṣèèṣì jẹ ọrẹ mímọ́ kan, ó gbọdọ̀ ṣe àtúnṣe lórí ẹbọ náà fún àlùfáà, kí ó sì fi ìdámárùn ún ohun tí ọrẹ náà jẹ́ kún un.

15. Àwọn àlùfáà kò gbọdọ̀ sọ ọrẹ mímọ́ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mú wá ṣíwájú Olúwa di àìmọ́.

16. Nípa fífi ààyè fún wọn láti jẹ ọrẹ mímọ́ náà, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ mú ẹ̀bi tí wọn yóò san nǹkan fún wá sórí wọn. Èmi ni Olúwa, tí ó sọ wọ́n di mímọ́.’ ”

17. Olúwa sọ fún Mósè pé,

18. “Sọ fún Árónì, àwọn ọmọ rẹ̀ àti fún gbogbo Ísírẹ́lì kí o sì wí fún wọn pé: ‘Bí ẹnikẹ́ni nínú yín yálà ọmọ Ísirẹ́lì ni tàbí àlejò tí ń gbé ní Ísírẹ́lì bá mú ẹ̀bùn wá fún ọrẹ ẹbọ sísun sí Olúwa, yálà láti san ẹ̀jẹ́ tàbí ọrẹ àtinúwá.

19. Ẹ gbọdọ̀ mú akọ láìní àbùkù láti ara màlúù, àgùntàn tàbí ewúrẹ́, kí ó baà lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún yín.

20. Ẹ má ṣe mú ohunkóhun tí ó ní àbùkù wá, torí pé kò ní jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún yín.

Ka pipe ipin Léfítíkù 22