Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Léfítíkù 22:29-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

29. “Nígbà tí ẹ bá rú ẹbọ ọpẹ́ sí Olúwa, ẹ rú u ní ọ̀nà tí yóò fí jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún yín.

30. Ẹ gbọdọ̀ jẹ ẹ́ ní ọjọ́ náà gan an: Ẹ má ṣe ṣẹ́ ọ̀kankan kù di àárọ̀. Èmi ni Olúwa.

31. “Ẹ pa òfin mi mọ́, kí ẹ sì máa ṣe wọ́n. Èmi ni Olúwa.

32. Ẹ má ṣe ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọdọ̀ mọ̀ mí ní mímọ́. Èmi ni Olúwa tí ó sọ yín di mímọ́.

33. Tí ó sì mú yín jáde láti Éjíbítì wá láti jẹ́ Ọlọ́run yín. Èmi ni Olúwa.”

Ka pipe ipin Léfítíkù 22