Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Léfítíkù 21:9-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. “ ‘Bí ọmọbìnrin àlùfáà bá ba ara rẹ̀ jẹ́ nípa sísọ ara rẹ̀ di aṣẹ́wó: ó dójú ti bàbá rẹ̀, a ó sun ún ní iná.

10. “ ‘Lẹ́yìn tí a ti fi òróró yan olórí àlùfáà láàrin àwọn arákùnrin rẹ̀ tí a sì ti fi amì òróró yàn láti máa wọ aṣọ àlùfáà, gbọdọ̀ tọ́jú irún orí rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ fa aṣọ rẹ̀ ya láti fihàn pé òun wà ní ipò ọ̀fọ̀.

11. Kí ó ma ṣe wọlé tọ òkú lọ, kí ó má ṣe sọ ará rẹ di àìmọ́ nítorí baba tàbí nítorí ìyá rẹ̀.

12. Kò gbọdọ̀ kúrò ní ibi mímọ́ Ọlọ́run tàbí kí ó sọ ọ́ di aláìmọ́ torí pé a ti fi ìfòróróyàn Ọlọ́run yà á sí mímọ́. Èmi ni Olúwa.

13. “ ‘Ọmọbìnrin tí yóò fẹ́ gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tí kò mọ Ọkùnrin rí.

14. Kò gbọdọ̀ fẹ́ opó tàbí ẹni tí a kọ̀ sílẹ̀ tàbí obìnrin tí ó ti fi àgbérè ba ara rẹ̀ jẹ́, ṣùgbọ́n kí ó fẹ́ obìnrin tí kò mọ ọkùnrin rí, láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀.

15. Kí ó má baà sọ di aláìmọ́ nínú àwọn ènìyàn rẹ̀. Èmi ni Olúwa tí ó sọ ọ́ di mímọ́.’ ”

16. Olúwa sì bá Mósè sọ̀rọ̀ pé,

17. “Sọ fún Árónì pé: ‘Ẹnikẹ́ni nínú ìran yín tí ó bá ní àrùn kan kò yẹ láti máa rú ẹbọ ohun jíjẹ́ fún mi.

Ka pipe ipin Léfítíkù 21