Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Léfítíkù 19:21-37 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Kí ọkùnrin náà mú àgbò kan wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé bí i ẹbọ ẹ̀bi sí Olúwa.

22. Àlùfáà yóò sì ṣe ètùtù fún un, pẹ̀lú àgbò ẹbọ ẹ̀bi náà níwájú Olúwa fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti ṣẹ̀. A ó sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ náà jìn-ní.

23. “ ‘Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ náà tí ẹ sì gbin igi eléso, kí ẹ ká èso wọn bí ohun èèwọ̀. Fún ọdún mẹ́ta ni kí ẹ kà á sí èèwọ̀, ẹ kò gbọdọ jẹ ẹ́

24. Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹrin, gbogbo èso wọ̀nyí yóò jẹ́ mímọ́, ọrẹ fún ìyìn Olúwa.

25. Ní ọdún karùn ún ni ẹ̀yin tó lè jẹ nínú èso igi náà, kí èso wọn ba à le máa pọ̀ sí i. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.

26. “ ‘Ẹ má ṣe jẹ ẹrankẹ́ran pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.“ ‘Ẹ kò gbọdọ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ yẹ̀míwò tàbí oṣó;

27. “ ‘Ẹ má ṣe dá òṣù sí àárin orí yín (fífá irun ẹ̀gbẹ́ orí, tí a ó sì dá irun àárin orí sí) tàbí kí ẹ ré orí irùngbọ̀n yín bí àwọn aláìkọlà ti ń ṣe.

28. “ ‘Ẹ má ṣe titorí òkú, gé ibi kankan nínú ẹ̀yà ara yín, Ẹ kò sì gbọdọ̀ sín gbẹ́rẹ́ kankan. Èmi ni Olúwa.

29. “ ‘Ẹ má ṣe ba ọmọbìnrin yín jẹ́ láti sọ ọ́ di aṣẹ́wó, kí ilẹ̀ yín má ba à di ti àgbérè, kí ó sì kún fún ìwà burúkú.

30. “ ‘Ẹ gbọdọ̀ máa pa ìsinmi mi mọ́ kí ẹ sì fi ọ̀wọ̀ fún ibi mímọ́ mi, Èmi ni Olúwa

31. “ ‘Ẹ má ṣe tọ abókúsọ̀rọ̀ tàbí àwọn àjẹ́ lọ, ẹ kò gbọdọ̀ tọ wọ́n lẹ́yìn láti jẹ́ kí wọ́n sọ yín di aláìmọ́. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.

32. “ ‘Fi ọ̀wọ̀ fún ọjọ́ orí arúgbó kí ẹ sì bọlá fún àwọn àgbàlagbà. Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run yín: Èmi ni Olúwa.

33. “ ‘Nígbà tí àjèjì kan bá ń gbé pẹ̀lú yín ní ilẹ̀ yín, ẹ má ṣe ṣe é ní ibi

34. kí àjèjì tí ń gbé pẹ̀lú yín dàbí onílé láàrin yín kí ẹ sì fẹ́ràn rẹ̀ bí i ara yín, torí pé ẹ̀yin ti jẹ́ àjèjì ní ilẹ̀ Éjíbítì rí. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.

35. “ ‘Ẹ má ṣe lo òsùwọ̀n èké, nígbà tí ẹ bá ń díwọ̀n yálà nípa òsùwọ̀n ọ̀pá, òsùwọ̀n ìwúwo tàbí òsùwọ̀n onínú.

36. Ẹ jẹ́ olódodo pẹ̀lú àwọn òsùwọ̀n yín òsùwọ̀n ìtẹ̀wọ̀n, òsùwọ̀n wíwúwo, òsùwọ̀n ìyẹ̀fun àti òsùwọ̀n nǹkan olómi yín ní láti jẹ́ èyí tí kò ní èrú nínú. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín tí ó mú yín jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì.

37. “ ‘Ẹ ó sì máa pa gbogbo àṣẹ àti òfin mi mọ́, ẹ ó sì máa ṣe wọ́n. Èmi ni Olúwa.’ ”

Ka pipe ipin Léfítíkù 19