Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Léfítíkù 18:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Olúwa sọ fún Mósè pé:

2. “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: ‘èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.

3. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe bí wọ́n ti ń ṣe ní Éjíbítì níbi tí ẹ ti gbé rí: bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe bí wọ́n ti ń ṣe ní ilẹ̀ Kénánì níbi tí èmi ń mú yín lọ. Ẹ kò gbọdọ̀ tẹ̀lé iṣe wọn.

4. Ẹ gbọdọ̀ tẹ̀lé òfin mi kí ẹ sì kíyèsí àti pa àṣẹ mi mọ́.

5. Ẹ pa àṣẹ àti òfin mi mọ́. Ẹni tí ó bá ṣe ìgbọ́ràn sí wọn yóò máa gbé nípa wọn, Èmi ni Olúwa.

6. “ ‘Ẹnikẹ́ni nínú yín kò gbọdọ̀ súnmọ́ ìbátan rẹ̀ láti bá a lòpọ̀, èmí ni Olúwa.

7. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ tàbùkù u bàbá rẹ nípa bíbá ìyá rẹ lòpọ̀, ìyá rẹ̀ ni, ìwọ kò gbọdọ̀ bá a lòpọ̀.

8. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ tàbùkù u bàbá rẹ nípa bíbá ìyàwó bàbá rẹ lòpọ̀: nítorí ìhòòhò bàbá rẹ ni.

9. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá arábìnrin rẹ tí ó jẹ́ ọmọ ìyá rẹ lòpọ̀, yálà a bí i nílé yín tàbí lóde.

Ka pipe ipin Léfítíkù 18