1. Olúwa sọ fún Mósè àti Árónì pé:
2. Ẹ bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀: kí ẹ wí fún wọn pé: Bí ìṣunjáde bá ń jáde lára ọkùnrin kan lójú ara: ìṣunjáde náà jẹ́ àìmọ́.
3. Yálà ó ń jáde léraléra tàbí ó dúró, èyí yóò sọ ọ́ di aláìmọ́. Báyìí ni ìṣunjáde rẹ̀ ṣe le è sọ ọ́ di aláìmọ́.
4. “ ‘Gbogbo ibùsùn tí irú ẹni tí ó ní ìṣunjáde náà bá sùn di àìmọ́.
5. Bí ẹnikẹ́ni bá fi ara kan ibùsùn rẹ̀, ó gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀. Yóò sì wà ní ipò àìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.
6. Ẹnikẹ́ni tí ó bá joko lórí ohunkóhun tí ọkùnrin tí ó ní ìṣunjáde bá jókòó le gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀: kí ó sì wẹ̀, kí ó sì wà láìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.
7. “ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan ọkùnrin náà tí ó ní ìṣunjáde gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóò sì di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.
8. “ ‘Bí ẹni tí ó ní ìṣunjáde bá tu itọ́ sí ẹni tí ó mọ́ lára, ẹni tí ó mọ́ náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀: yóò sì wà nípò àìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.
9. “ ‘Gàárì ẹranko tí ẹni náà bá gùn yóò di àìmọ́.
10. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan ohunkóhun tí ó wà lábẹ́ ọkùnrin náà di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá mú irú nǹkan bẹ́ẹ̀ gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó wẹ ara rẹ̀. Yóò sì jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.
11. “ ‘Ẹnikẹ́ni tí ọkùnrin tí ó ní ìṣunjáde ní ara rẹ̀ bá farakàn láì fi omi fọ ọwọ́ rẹ̀, gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀. Yóò sì wà ní ipò àìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.