Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Léfítíkù 14:44-52 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

44. Àlùfáà yóò tún lọ yẹ̀ ẹ́ wò bí àrùn náà bá tún gbilẹ̀ sí i nínú ilé náà: ẹ̀tẹ̀ apanirun ni èyí, ilé náà jẹ́ aláìmọ́.

45. Wíwó ni kí a wó o, gbogbo òkúta ilé náà, àwọn igi àti gbogbo ohun tí a fi rẹ́ ẹ ni kí a kó jáde nínú ìlú sí ibi tí a kà sí àìmọ́.

46. “Ẹni tí ó bá wọ inú ilé náà lẹ́yìn tí a ti tì í, yóò di aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.

47. Ẹni tí ó bá sùn nínú ilé náà tàbí tí ó bá jẹun nínú rẹ̀ gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀.

48. “Bí àlùfáà bá wá yẹ̀ ẹ́ wò tí àrùn náà kò gbilẹ̀ mọ́ lẹ́yìn tí a ti rẹ́ ilé náà: kí àlùfáà pe ilé náà ní mímọ́, torí pé àrùn náà ti lọ.

49. Láti sọ ilé yìí di mímọ́. Àlùfáà yóò mú ẹyẹ méjì àti igi sídà òdòdó àti hísópù.

50. Yóò sì pa ọ̀kan nínú àwọn ẹyẹ náà sorí omi tí ó mọ́ nínú ìkòkò amọ̀.

51. Kí ó ri igi sídà, hísópù, òdòdó àti ààyè ẹyẹ náà bọ inú ẹ̀jẹ̀ òkú ẹyẹ àti omi tí ó mọ́ náà kí ó fi wọ́n ilẹ náà lẹ́ẹ̀méje.

52. Yóò fi ẹ̀jẹ̀ ẹyẹ náà, omi tí ó mọ́, ààyè ẹyẹ, igi sídà, hisopu àti òdòdó sọ ilé náà di mímọ́.

Ka pipe ipin Léfítíkù 14