Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 9:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nísinsinyìí, nígbà tí gbogbo ọba tó wà ní ìwọ̀-oòrùn Jọ́dánì gbọ́ nípa nǹkan wọ̀nyí, àwọn náà tí ó wà ní orí òkè àti àwọn tí ó wà ní ẹṣẹ̀ òkè, àti gbogbo àwọn tí ó wà ní agbégbé Òkun ńlá títí ó fi dé Lẹ́bánónì (àwọn ọba Hítì Ámórì, Kénánì, Pérísì Hífì àti Jébúsì)

2. wọ́n sì kó ara wọn jọ láti bá Jósúà àti Ísírẹ́lì jagun.

3. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ènìyàn Gíbíónì gbọ́ ohun tí Jóṣúà ṣe sí Jẹ́ríkò àti Áì,

4. wọ́n dá ọgbọ́n ẹ̀tàn. Wọ́n lọ bí aṣojú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn: tí kún fún àwọn àpò tó ti gbó, àti àwọn awọ ọtí wáìnì tó ti gbó tí a tún rán.

5. Àwọn ọkùnrin náà sì wọ bàtà àti aṣọ tí ó ti gbó. Gbogbo oúnjẹ tí wọ́n pèsè fún ara wọn sì bu.

6. Wọ́n sì tọ Jóṣúà lọ ní ibùdó ní Gílígálì, wọ́n sì sọ fún òun àti àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì pé, “Ìlú òkèrè ní àwọn ti wá, ẹ ṣe àdéhùn àlàáfíà pẹ̀lú wa.”

7. Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sọ fún àwọn ará Hífì pé, “Ṣùgbọ́n bóyá tòsí wa ni ẹ ń gbé. Báwo ni a ó ṣe lè se àdéhùn pẹ̀lú yín?”

8. “Ìránṣẹ́ rẹ ní àwa í ṣe.” Wọ́n sọ fún Jóṣúà.Ṣùgbọ́n Jóṣúà béèrè, “Ta ni yín àti pé níbo ni ẹ̀yín ti wá?”

Ka pipe ipin Jóṣúà 9