Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 6:22-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Jóṣúà sì sọ fún àwọn ọkùnrin méjì tí wọ́n ti wá ṣe ayọlẹ̀ náà wò pé, “Ẹ lọ sí ilé aṣẹ́wó nì, kí ẹ sì mu jáde àti gbogbo ohun tí í ṣe tirẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ tí búra fún un.”

23. Bẹ́ẹ̀ ní àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó lọ ṣe ayọ́lẹ̀wò wọlé lọ, wọ́n sì mú Ráhábù jáde, baba rẹ̀, ìyá rẹ̀, àwọn arákùnrin rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó ní. Wọ́n sì mú gbogbo ìdílé rẹ̀ jáde, wọ́n sì fi wọ́n sí ibìkan ní ìta ibùdó àwọn ará Ísírẹ́lì.

24. Nígbà náà ni wọ́n ṣun gbogbo ìlú náà àti gbogbo ohun tí ó wà nínú u rẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n fi fàdákà, wúrà ohun èlò-idẹ àti irin sínú ìsúra ilé Olúwa.

25. Ṣùgbọ́n Jóṣúà dá Ráhábù asẹ́wó pẹ̀lú gbogbo ìdílé e rẹ̀ àti gbogbo ẹni tí í ṣe tirẹ̀ sí nítorí pé, ó pa àwọn ọkùnrin tí Jóṣúà rán gẹ́gẹ́ bí ayọ́lẹ̀wò sí Jẹ́ríkò mọ́. Ó sì ń gbé láàrin ará Ísírẹ́lì títí di òní yìí.

26. Ní àkókò náà Jóṣúà sì búra pé; “Ègún ni fún ẹni náà níwájú Olúwa tí yóò dìde, tí yóò sì tún ìlú Jẹ́ríkò kọ́:“Pẹ̀lú ikú àkọ́bí ọmọ rẹ̀ niyóò fi pilẹ̀ rẹ̀;ikú àbíkẹ́yìn in rẹ̀ ní yóò figbé ìlẹ̀kùn bodè rẹ̀ ró.”

27. Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wà pẹ̀lú Jóṣúà; òkìkí rẹ̀ sì kàn ká gbogbo ilẹ̀ náà.

Ka pipe ipin Jóṣúà 6