Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 6:16-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Ní ìgbà kéje, nígbà tí àwọn àlùfáà fọn fèrè, Jóṣúà pàṣẹ fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ hó! Nítorí pé Olúwa ti fún un yín ní ìlú náà.

17. Ìlú náà àti gbogbo ohun tí ó wà níbẹ̀ ni yóò jẹ́ ìyàṣọ́tọ̀ fún Olúwa. Ráhábù tí ó jẹ́ panṣágà nìkan àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú u rẹ̀ ni a ó dásí; nítorí tí ó pa àwọn ayọ́lèẹ̀wò tí á rán mọ́.

18. Ẹ pa ara yín mọ́ kúrò nínú ohun ìyàsọ́tọ̀ fún ìparun, kí ẹ̀yin kí ó má ba à ṣojú kòkòrò nípa mímú nínú àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀. Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ ẹ ó sọ ibùdó Ísírẹ́lì di ìparun. Kí ẹ sì mú wàhálà wá sórí i rẹ̀.

19. Gbogbo fàdákà àti wúrà àti ohun èlò idẹ àti irin jẹ́ mímọ́ fún Olúwa, wọ́n yóò wá sínú ìsúra Olúwa.”

20. Nígbà tí àwọn àlùfáà fọn ìpè, àwọn ènìyàn náà sì hó Ó sì ṣe, bí àwọn ènìyàn ti gbọ́ ìró ìpè, tí àwọn ènìyàn sì hó ìhó-ńlá, odi ìlú náà wó lulẹ̀ bẹẹrẹ; bẹ́ẹ̀ ni olúkúlùkù ya wọ inú ìlú náà lọ tààrà, wọ́n sì kó ìlú náà.

21. Wọ́n ya ìlú náà sọ́tọ̀ fún Olúwa àti fún ìparun, wọ́n sì fi idà run gbogbo ohun alààyè ní ìlú náà—ọkùnrin àti obìnrin, ọ́mọdé, àti àgbà, màlúù, àgùntàn àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.

Ka pipe ipin Jóṣúà 6