Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 6:1-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Wàyí oí a ti há Jẹ́ríkò mọ́lé nítorí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ẹnikẹ́ni kò jáde, ẹnikẹ́ni kò sì wọlé.

2. Nígbà náà ni Olúwa wí fún Jóṣúà pé, “Wò ó, mo ti fi Jẹ́ríkò lé ọ lọ́wọ́ pẹ̀lú ọba rẹ̀ àti àwọn jagunjagun rẹ̀.

3. Ẹ wọ́de ogun yí ìlú náà ká lẹ́ẹ̀kan pẹ̀lú gbogbo àwọn jagunjagun. Ẹ ṣe èyí fún ọjọ́ mẹ́fà.

4. Jẹ́ kí àwọn àlùfáà méje gbé fèrè ìwo àgbò ní iwájú àpótí ẹ̀rí. Ní ọjọ́ kéje. Ẹ wọ́de ogun yí ìlú náà ká ní ìgbà méje, pẹ̀lú àwọn àlùfáà tí ń fọn fèrè.

5. Nígbà tí ẹ bá gbọ́ ohùn un fèrè náà, kí àwọn ènìyàn hó-yèè ní igbe ńlá, nígbà náà ni odi ìlú náà yóò sì wó lulẹ̀, àwọn ènìyàn yóò sì lọ sí òkè, olúkúlùkù yóò sì wọ inú rẹ̀ lọ tààrà.”

6. Bẹ́ẹ̀ ni Jóṣúà ọmọ Núnì pe àwọn àlùfáà ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa náà kí àwọn àlùfáà méje tí ó ru fèrè ìwo wà ní iwájú u rẹ̀.”

7. Ó sì pàṣẹ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ lọ, kí ẹ sì yí ìlú náà ká pẹ̀lú àwọn olùsọ́ tí ó hámọ́ra kọjá ní iwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa.”

8. Nígbà tí Jóṣúà ti bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ tán, àwọn àlùfáà méje tí wọ́n gbé fèrè méje ní iwájú Olúwa kọjá sí iwájú, wọ́n sì fọn fèrè wọn, àpótí ẹ̀rí Olúwa sì tẹ̀-lé wọn.

9. Àwọn olùṣọ tí ó hámọ́ra sì lọ níwájú àwọn àlùfáà tí ń fọn fèrè, olùṣọ́ ẹ̀yìn sì tẹ̀-lé àpótí ẹ̀rí náà. Ní gbogbo àsìkò yìí fèrè sì ń dún.

10. Ṣùgbọ́n Jóṣúà tí pàṣẹ fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ kò gbọdọ̀ kí-gbe ogun, ẹ kò gbọdọ̀ gbé ohùn yín sókè, ẹ má ṣe sọ ọ̀rọ̀ kan títí ọjọ́ tí èmi yóò sọ fún un yín pé kí ẹ hó. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò sì hó!”

11. Bẹ́ẹ̀ ni ó mú kí àpótí ẹ̀rí Olúwa yí ìlú náà ká, ó sì yí i ká lẹ́ẹ̀kan. Nígbà náà ni àwọn ènìyàn náà padà sí ibùdó wọ́n sì gbé ibẹ̀ fún alẹ́ náà.

12. Jóṣúà sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, àwọn àlùfáà sì gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa.

13. Àwọn àlùfáà méje tí ó gbé ìpè ìwo àgbò méje ń lọ níwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa, wọ́n sì ń fọ́n àwọn ìpè: àwọn tí ó há mọ́ra ogun ń lọ níwájú u wọn; àwọn ọmọ tó wà lẹ́yìn sì ń tọ àpótí ẹ̀rí Olúwa lẹ́yìn, àwọn àlùfáà sì ń fọn ìpè bí wọ́n ti ń lọ.

14. Ní ọjọ́ kéjì, wọ́n yí ìlú náà ká lẹ́ẹ̀kan wọ́n sì padà sí ibùdó. Wọ́n sì ṣe èyí fún ọjọ́ mẹ́fà.

15. Ní ọjọ́ kéje, wọ́n dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ní àfẹ̀mọ́júmọ́, wọ́n sì wọ́de ogun yí ìlú náà ká ní ìgbà méje, gẹ́gẹ́ bí i ti ìṣáájú, ní ọjọ́ kéje nìkanṣoṣo ni wọ́n wọ́de ogun yí ìlú náà ká nígbà méje.

Ka pipe ipin Jóṣúà 6