Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 4:12-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Àwọn ọkùnrin Rúbẹ́nì, Gádì àti ìdajì ẹ̀yà Mànásè náà sì rékọjá ní ìhámọ́ra ogun níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, gẹ́gẹ́ bí Móṣè ti pàṣẹ fún wọn.

13. Àwọn bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì (40,000) tó ti múra fún ogun rékọjá lọ ní iwájú Olúwa sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹ́ríkò láti jagun.

14. Ní ọjọ́ náà ni Olúwa gbé Jóṣúà ga ní ojú gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n sì bẹ̀rù u rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé e wọn, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti bẹ̀rù Móṣè.

15. Olúwa sì sọ fún Jóṣúà pé,

16. “Pàṣẹ fún àwọn àlùfáà tí o ń ru àpótí ẹ̀rí, kí wọn kí ó jáde kúrò nínú odò Jọ́dánì.”

17. Bẹ́ẹ̀ ni Jóṣúà pàṣẹ fún àwọn àlùfáà pé, “Ẹ jáde kúrò nínú odò Jọ́dánì.”

18. Àwọn àlùfáà náà jáde láti inú odò pẹ̀lú apòtí ẹ̀rí ni orí wọn. Bí wọ́n ti fi ẹṣẹ̀ ẹ wọn tẹ orí ilẹ̀ gbígbẹ ni omi Jọ́dánì náà padà sí àyè e rẹ̀, o sì kún wọ bèbè bí i ti àtẹ̀yìn wá.

19. Ní ọjọ́ kẹwàá (10) osù kìn-ní-ní (1) àwọn ènìyàn náà lọ láti Jọ́dánì, wọ́n sì dúró ní Gílígálì ní ìlà-oòrùn Jẹ́ríkò.

20. Jóṣúà sì to àwọn òkúta méjìlá (12) tí wọ́n mú jáde ní Jọ́dánì jọ ní Gílígálì.

21. Ó sì sọ fún àwọn ará Ísírẹ́lì, “Ní ọjọ́ iwájú nígbà tí àwọn ọmọ yín bá béèrè ní ọwọ́ baba wọn pé, ‘Kí ni òkúta wọ̀nyí yìí dúró fún?’

22. Nígbà náà ni ẹ ó jẹ́ kí àwọn ọmọ yín mọ̀ pé, ‘Ísírẹ́lì rékọjá odò Jọ́dánì ní orí ilẹ̀ gbígbẹ.’

23. Nítorí Olúwa Ọlọ́run yín mú Jọ́dánì gbẹ ní iwájú u yín títí ẹ̀yin fi kọjá. Olúwa Ọlọ́run yín ti ṣe sí Jọ́dánì gẹ́gẹ́ bí ó ti se sí Òkun Pupa, nígbà tí ó mú un gbẹ ní iwájú wa títí àwa fi kọjá.

24. Ó ṣe èyí kí gbogbo ayé lè mọ̀ pé ọwọ́ Olúwa ní agbára, àti kí ẹ̀yin kí ó lè máa bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run yín ní ìgbà gbogbo.”

Ka pipe ipin Jóṣúà 4