Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 21:3-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì fún àwọn ọmọ Léfì ní àwọn ìlú wọ̀nyí, àti ilẹ̀ pápá oko tútù lára ilẹ̀ ìní ti wọn gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè.

4. Ìpín kìn-ín-ni wà fún àwọn ọmọ Kóhátì, ní agbo ilé, agbo ilé. Àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n jẹ́ ọmọ Árónì àlùfáà ni a pín ìlú mẹ́talá fún láti ara Símónì àti Bẹ́ńjámínì.

5. Ìyòókù àwọn ọmọ Kóhátì ni a pín ìlú mẹ́wàá fún láti ara ẹ̀yà Éfúráímù, Dánì àti ìdajì Mánásè.

6. Àwọn ẹ̀yà Gásónì ni a pín ìlú mẹ́talá fún láti ara ẹ̀yà Ísákárì, Áṣíérì, Náfitalì àti ìdajì ẹ̀yà Mánásè ní Básánì.

7. Àwọn ọmọ Mérárì ní agbo ilé, agbo ilé ni wọ́n fún ní ìlú méjìlá láti ara ẹ̀yà Rúbẹ́nì, Gádì àti Sébúlónì.

8. Báyìí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pín ìlú wọ̀nyí àti ilẹ̀ pápá oko tutù fún àwọn ọmọ Léfì gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ láti ẹnu Móse.

9. Láti ara ẹ̀yà Júdà àti ẹ̀yà Síméónì ni wọ́n ti pín àwọn ìlú tí a dárúkọ wọ̀nyí,

10. (Ilú wọ̀nyí ni a fún àwọn ọmọ Árónì tí ó jẹ́ ọ̀kan nínú ìdílé Kóhátì tí í ṣe ọmọ Léfì, nítorí tí ìpín àkọ́kọ́ jẹ́ ti wọn).

11. “Wọ́n fún wọn ní Kiriati Áríbà (tí í ṣe, Hébúrónì), pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù tí ó yí wọn ká, ní ilẹ̀ òkè Júdà. (Áríbà ni baba ńlá Ánákì.)

12. Ṣùgbọ́n àwọn oko àti àwọn abúlé ní agbégbé ìlú náà ni wọ́n ti fi fún Kélẹ́bù ọmọ Jéfúnè gẹ́gẹ́ bí ohun ìní rẹ̀.

13. Ní àfikún wọ́n sì fún àwọn ọmọ Árónì tí í ṣe àlùfáà ní Hébúrónì (ọ̀kannínú ìlú ààbò fún àwọn apàníyàn) pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù rẹ̀, Líbínà,

14. Játírì, Ésítẹ́móà,

15. Hólónì àti Débírì,

16. Háínì, Jútà àti Bẹti-Sẹ́mẹ́sì, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn. Ìlú mẹ́sàn án láti ara ẹ̀yà méjì wọ̀nyí.

17. Láti ara ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ni wọ́n ti fún wọn ní Gíbíónì, Gẹ́bà,

18. Ánatótì àti Álímónì, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn, wọ́n jẹ́ ìlú mẹ́rin.”

19. Gbogbo ìlú àwọn àlùfáà, ìran Árónì, jẹ́ mẹ́talá, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá wọn.

20. Ìyòókù ìdílé Kóhátì tí ó jẹ́ ọmọ Léfì ní a pín ìlú fún láti ara ẹ̀yà Éfúráímù.

Ka pipe ipin Jóṣúà 21