Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 21:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Báyìí ni olórí ìdílé àwọn ọmọ Léfì lọ bá Élíásárì àlùfáà, Jóṣúà ọmọ Núnì àti olórí ẹ̀yà àwọn ìdílé ẹ̀yà Ísírẹ́lì

2. Ní Sílò, ní Kénánì, wọn sọ fún wọn pé, “Olúwa pàṣẹ nípasẹ̀ Mósè pé kí wọn fún wa ní ìlú láti máa gbé àti ilẹ̀ pápá oko tútù fún ẹran ọ̀sìn wa.”

3. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì fún àwọn ọmọ Léfì ní àwọn ìlú wọ̀nyí, àti ilẹ̀ pápá oko tútù lára ilẹ̀ ìní ti wọn gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè.

4. Ìpín kìn-ín-ni wà fún àwọn ọmọ Kóhátì, ní agbo ilé, agbo ilé. Àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n jẹ́ ọmọ Árónì àlùfáà ni a pín ìlú mẹ́talá fún láti ara Símónì àti Bẹ́ńjámínì.

5. Ìyòókù àwọn ọmọ Kóhátì ni a pín ìlú mẹ́wàá fún láti ara ẹ̀yà Éfúráímù, Dánì àti ìdajì Mánásè.

6. Àwọn ẹ̀yà Gásónì ni a pín ìlú mẹ́talá fún láti ara ẹ̀yà Ísákárì, Áṣíérì, Náfitalì àti ìdajì ẹ̀yà Mánásè ní Básánì.

7. Àwọn ọmọ Mérárì ní agbo ilé, agbo ilé ni wọ́n fún ní ìlú méjìlá láti ara ẹ̀yà Rúbẹ́nì, Gádì àti Sébúlónì.

8. Báyìí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pín ìlú wọ̀nyí àti ilẹ̀ pápá oko tutù fún àwọn ọmọ Léfì gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ láti ẹnu Móse.

9. Láti ara ẹ̀yà Júdà àti ẹ̀yà Síméónì ni wọ́n ti pín àwọn ìlú tí a dárúkọ wọ̀nyí,

10. (Ilú wọ̀nyí ni a fún àwọn ọmọ Árónì tí ó jẹ́ ọ̀kan nínú ìdílé Kóhátì tí í ṣe ọmọ Léfì, nítorí tí ìpín àkọ́kọ́ jẹ́ ti wọn).

Ka pipe ipin Jóṣúà 21