Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 18:17-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Nígbà náà ni ó yípo sí ìhà àríwá, ó sì lọ sí Ẹni Ṣẹ́mẹ́sì, ó tẹ̀ṣíwájú dé Gélíótì tí ó kọjú sí òkè Pasi Ádúmímù, ó sì sọ̀kalẹ̀ sí ibi Okúta Bóhánì ọmọ Rúbẹ́nì.

18. Ó tẹ̀ṣíwájú títí dé gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Bẹti-Árábà, ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí aginjù.

19. Nígbà náà ni ó lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Bẹti-Hógíládì, ó sì jáde ní àríwá etí bèbè Òkun Iyọ̀, ní ẹnu odò Jọ́dánì ní gúsù. Èyí ni ààlà ti gúsù.

20. Odò Jọ́dánì sí jẹ́ ààlà ní ìhà ìlà-oòrùn.Ìwọ̀nyí ní àwọn ààlà ti ó ṣàmì sí ìní àwọn ìdílé Bẹ́ńjámínì ní gbogbo àwọn àyíká wọn.

21. Ẹyà Bẹ́ńjámínì ní agbo ilé, agbo ilé ni àwọn ìlú wọ̀nyí:Jẹ́ríkò, Bẹti-Hógílà, Emeki-Késísì,

22. Bẹti-Árábà, Sẹ́máráímù, Bẹ́tẹ́lì,

23. Áfímù, Párà, Ófírà

24. Kẹ́fárì, Ámónì, Ófínì àti Gébà, àwọn ìlú méjìlá àti ìletò wọn.

Ka pipe ipin Jóṣúà 18