Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 18:16-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Ààlà náà lọ sí ìṣàlẹ̀ ẹṣẹ̀ òkè tí ó kọjú sí Àfonífojì Bẹni-Hínómù, àríwá Àfonífojì Réfáímù O sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí Àfonífojì Hínómù sí apá gúsù gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè ìlú Jébúsì, ó sì lọ bẹ́ẹ̀ títí dé Ẹbi Rósẹ́lì.

17. Nígbà náà ni ó yípo sí ìhà àríwá, ó sì lọ sí Ẹni Ṣẹ́mẹ́sì, ó tẹ̀ṣíwájú dé Gélíótì tí ó kọjú sí òkè Pasi Ádúmímù, ó sì sọ̀kalẹ̀ sí ibi Okúta Bóhánì ọmọ Rúbẹ́nì.

18. Ó tẹ̀ṣíwájú títí dé gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Bẹti-Árábà, ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí aginjù.

19. Nígbà náà ni ó lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Bẹti-Hógíládì, ó sì jáde ní àríwá etí bèbè Òkun Iyọ̀, ní ẹnu odò Jọ́dánì ní gúsù. Èyí ni ààlà ti gúsù.

20. Odò Jọ́dánì sí jẹ́ ààlà ní ìhà ìlà-oòrùn.Ìwọ̀nyí ní àwọn ààlà ti ó ṣàmì sí ìní àwọn ìdílé Bẹ́ńjámínì ní gbogbo àwọn àyíká wọn.

21. Ẹyà Bẹ́ńjámínì ní agbo ilé, agbo ilé ni àwọn ìlú wọ̀nyí:Jẹ́ríkò, Bẹti-Hógílà, Emeki-Késísì,

22. Bẹti-Árábà, Sẹ́máráímù, Bẹ́tẹ́lì,

23. Áfímù, Párà, Ófírà

24. Kẹ́fárì, Ámónì, Ófínì àti Gébà, àwọn ìlú méjìlá àti ìletò wọn.

25. Gíbíónì, Rámà, Béérótì,

26. Mísípà, Kéfírà, Mósà,

27. Rẹ́kẹ́mù, Írípẹ́ẹ́lì, Tárálà,

28. Sélà, Háléfì, ìlú Jébúsì (tí íse Jérúsálẹ́mù), Gíbíà àti Kíríátì, àwọn ìlú mẹ́rìnlá àti ìletò wọn.Èyí ni ìní Bẹ́ńjámínì fún ìdílé rẹ̀.

Ka pipe ipin Jóṣúà 18