Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 18:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì péjọ ní Ṣílò, wọ́n si kó Àgọ́ Ìpàdé ní ibẹ̀ Gbogbo ilẹ̀ náà sì wà ní abẹ́ àkóso wọn,

2. ṣùgbọ́n ó ku ẹ̀yà méje nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí kò tí ì gba ogún ìní wọn.

3. Báyìí ni Jóṣúà sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì: “Báwo ni ẹ̀yin yóò ṣe dúró pẹ́ tó, kí ẹ tó gba ilẹ̀ ìní tí Olúwa, Ọlọ́run àwọn baba yín ti fi fún yín?

Ka pipe ipin Jóṣúà 18