Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 16:7-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Láti Jánóà ó yípo lọ sí gúsù sí Átarótì àti Náárà, ó sì dé Jẹ́ríkò, ó sì pin sí odò Jọ́dánì.

8. Láti Tápúà ààlà náà sì lọ sí ìhà ìwọ̀-oòrùn, ní Kana-Ráfínì, ó sì parí ní òkun. Èyí ni ìní ẹ̀yà àwọn ọmọ Éfúráímù, ní agbo ilé agbo ilé.

9. Ó tún mú àwọn ìlú àti ìletò wọn tí ó yà sọ́tọ̀ fún àwọn ọmọ Éfúráímù tí ó wà ní àárin ìní àwọn ọmọ Mánásè.

10. Wọn kò lé àwọn ara Kénánì tí ń gbé ni Gésérì kúrò, titi di oni yìí ni àwọn ara Kébáni ń gbé láàárin àwọn ènìyàn Éfúráímù, Ṣùgbọ́n wọ́n mú wọ́n sìn.

Ka pipe ipin Jóṣúà 16