4. Báyìí ni Mànásè àti Éfúráímù, àwọn ọmọ Jósẹ́fù gba ilẹ̀ ìní wọn.
5. Èyí ni ilẹ̀ Éfúráímù, ní agbo ilé agbo ilé:Ààlà ìní wọn lọ láti Atarotu-Ádárì ní ìlà oòrùn lọ sí Okè Bẹti-Hórónì.
6. Ó sì lọ títí dé òkun. Láti Míkímétatì ní ìhà àríwá, ó sì yí lọ sí ìhà ìlà-oòrùn lọ sí Taanati-Sílò, ó sì kọjá ní ẹ̀bá rẹ̀ lọ sí Jánóà ní ìlà-oòrùn.
7. Láti Jánóà ó yípo lọ sí gúsù sí Átarótì àti Náárà, ó sì dé Jẹ́ríkò, ó sì pin sí odò Jọ́dánì.
8. Láti Tápúà ààlà náà sì lọ sí ìhà ìwọ̀-oòrùn, ní Kana-Ráfínì, ó sì parí ní òkun. Èyí ni ìní ẹ̀yà àwọn ọmọ Éfúráímù, ní agbo ilé agbo ilé.
9. Ó tún mú àwọn ìlú àti ìletò wọn tí ó yà sọ́tọ̀ fún àwọn ọmọ Éfúráímù tí ó wà ní àárin ìní àwọn ọmọ Mánásè.
10. Wọn kò lé àwọn ara Kénánì tí ń gbé ni Gésérì kúrò, titi di oni yìí ni àwọn ara Kébáni ń gbé láàárin àwọn ènìyàn Éfúráímù, Ṣùgbọ́n wọ́n mú wọ́n sìn.