Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 1:15-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. títí Olúwa yóò fi fún wọn ní ìsinmi, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe fún un yín, àti títí tí àwọn pẹ̀lú yóò fi gba ilẹ̀ náà tí Olúwa Ọlọ́run yín fi fún wọn. Lẹ́yìn náà, ẹ̀yin lè padà sí ilẹ̀ ìní in yín, tí Mósè ìránṣẹ́ Olúwa fi fún un yin, ní agbégbé ìlà-óòrùn ti Jọ́dánì.”

16. Nígbà náà ni wọ́n dá Jósúà lóhùn pé, “Ohunkóhun tí ìwọ pa láṣẹ fún wa ni àwa yóò ṣe; ibikíbi tí ìwọ bá rán wa ni àwa yóò lọ.

17. Gẹ́gẹ́ bí àwa ti gbọ́ran sí Móṣè nínú ohun gbogbo, bẹ́ẹ̀ ni àwa yóò máa gbọ́ tìrẹ. Kí Olúwa Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lúù rẹ, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà pẹ̀lú u Móṣè.

18. Ẹnikẹ́ni tí ó bá tàpá sí ọ̀rọ̀ rẹ, tí kò sì ṣe ìgbọràn sí ọ̀rọ̀ rẹ, nínú ohun gbogbo tí ìwọ yóò paláṣẹ fún wọn, pípa ni a ó pa á. Kí ìwọ ṣáà ṣe gírí, kí ó sì mú àyà le!”

Ka pipe ipin Jóṣúà 1