Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 9:7-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Ó pàṣẹ fún oòrùn kò sì le è rànkí ó sì dí ìmọ́lẹ̀ ìràwọ̀ mọ́.

8. Òun nìkanṣoṣo ni ó na ojú ọ̀run lọ,ti ó sì ń rìn lórí ìgbì òkun.

9. Ẹni tí ó dá ìràwọ̀ Béárì, Óríónìàti Píléíádè àti yàrá púpọ̀ ti gúsù.

10. Ẹni tí ń ṣe ohun tí ó tóbi jù àwàrí lọ,àní ohun ìyanu láìní iye.

11. Kíyèsí i, ó ń kọjá lọ ní ẹ̀bá ọ̀dọ̀ mi,èmi kò sì rí i, ó sì kọjá síwáju,bẹ́ẹ̀ ni èmi kò rí ojú rẹ̀.

12. Kiyèsí i, ó já a gbà lọ, ta ni ó lè fà á padà?Ta ni yóò bi í pé kí ni ìwọ ń ṣe nì?

13. Ọlọ́run kò ní fa ìbínú rẹ̀ sẹ́yìn,àwọn oní rànlọ́wọ́ ti Ráhábù a sì tẹriba lábẹ́ rẹ̀.

14. “Kí ní ṣe tí èmi ò fi dá a lóhùn?Tí èmi kò fi máa fi ọ̀rọ̀ àwàwí mi ṣe àwsíyé fún-un?

15. Bí ó tilẹ̀ ṣe pé mo ṣe aláìlẹ́bi,èmi kò gbọdọ̀ dá a lóhùn,ṣùgbọ́n èmi ó gbàdúrà fún àánú.

16. Bí èmi bá sì ké pè é, tí Òun sì dá mi lóhùn,èmi kì yóò sì gbàgbọ́ pé, Òun ti fetí sí ohùn mi.

17. Nítorí pé òun yóò lọ̀ mi lúúlúú pẹ̀lú ìjì ńláó sọ ọgbẹ́ mi di pupọ̀ láìnídìí.

18. Òun kì yóò jẹ́ kí èmi kí ó rí ẹ̀mí mi,ṣùgbọ́n ó mú ohun kíkorò kún un fún mi.

19. Bí mo bá sọ ti agbára, wò ó!Alágbára ni, tàbí ńi ti ìdájọ́, ta ni yóò dá àkókò fún mi láti rò?

20. Bí mo tilẹ̀ dá ara mi láre, ẹnu ara mi óò dá mi lẹ́bi;bí mo wí pé olódodo ni èmi yóò sì fi mí hàn ní ẹni ẹ̀bi.

21. “Olóòótọ́ ni mo ṣe,síbẹ̀ èmi kò kíyèsí ara mi,ayé mi ní èmi ìbá máa gàn.

22. Ohùn kan náà ni, nítorí náà ni èmi se sọ:‘Òun a pa ẹni òtítọ́ àti ènìyàn búburú pẹ̀lú.’

23. Bí ìjàǹbá bá pani lójijì,yóò rẹ́rín-ín ìdàwọ́ aláìṣẹ̀.

Ka pipe ipin Jóòbù 9