29. Bí ó bá ṣe pé ènìyàn búburú ni èmi,ǹjẹ́ kí ni èmi ń ṣe làálàá lásán sí?
30. Bí mo tilẹ̀ fi ọṣẹ ojú dídì wẹ ara mi,tí mo fi omi àrò wẹ ọwọ́ mi mọ́,
31. ṣíbẹ̀ ìwọ ó gbé mi wọ inú ihòọ̀gọ̀dọ̀ aṣọ ara mi yóò sọ mi di ìríra.
32. “Nítorí Òun kì í ṣe ènìyàn bí èmi,tí èmi ó fi dá a lóhùn tí àwa o fi pàdé ní ìdájọ́.
33. Bẹ́ẹ̀ ni kò sí alátúnṣe kan ní agbede-méjì watí ìbá fi ọwọ́ rẹ̀ lé àwa méjèèjì lára.
34. Kí ẹnìkan ṣá à mú ọ̀pá Ọlọ́run kúrò lára mi,kí ìbẹ̀rù rẹ̀ kí ó má sì se dáyà fò mí
35. Nígbà náà ni èmi ìbá sọ̀rọ̀, èmi kì bá sì bẹ̀rù rẹ̀;ṣùgbọ́n bí ó tí dáré-ti mi, kò ri bẹ́ẹ̀ fún mi.