Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 9:20-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Bí mo tilẹ̀ dá ara mi láre, ẹnu ara mi óò dá mi lẹ́bi;bí mo wí pé olódodo ni èmi yóò sì fi mí hàn ní ẹni ẹ̀bi.

21. “Olóòótọ́ ni mo ṣe,síbẹ̀ èmi kò kíyèsí ara mi,ayé mi ní èmi ìbá máa gàn.

22. Ohùn kan náà ni, nítorí náà ni èmi se sọ:‘Òun a pa ẹni òtítọ́ àti ènìyàn búburú pẹ̀lú.’

23. Bí ìjàǹbá bá pani lójijì,yóò rẹ́rín-ín ìdàwọ́ aláìṣẹ̀.

24. Nígbà tí a bá fi ayé lé ọwọ́ ènìyàn búburú;ó sì bo àwọn onídàájọ́ rẹ̀ lójú;bí kò bá rí bẹ́ẹ̀ ǹjẹ́ ta ni?

25. “Ǹjẹ́ nísinsìn yìí ọjọ́ mi yára ju oníṣẹ́ lọ,wọ́n fò lọ, wọn kò rí ayọ̀.

26. Wọ́n kọjá lọ bí ọkọ̀ eésú tí ń ṣúré lọ;bí idì tí ń yára si ohùn ọdẹ.

27. Bí èmi bá wí pé, ‘Èmi ó gbàgbé arò ìbìnújẹ́ mi,èmi ó fi ọkàn lélẹ̀, èmi ó sì rẹ ara mi lẹ́kún.’

28. Ẹ̀rù ìbànújẹ́ mi gbogbo bà mí,èmi mọ̀ pé ìwọ kì yóò mú mi bí aláìṣẹ̀.

29. Bí ó bá ṣe pé ènìyàn búburú ni èmi,ǹjẹ́ kí ni èmi ń ṣe làálàá lásán sí?

30. Bí mo tilẹ̀ fi ọṣẹ ojú dídì wẹ ara mi,tí mo fi omi àrò wẹ ọwọ́ mi mọ́,

31. ṣíbẹ̀ ìwọ ó gbé mi wọ inú ihòọ̀gọ̀dọ̀ aṣọ ara mi yóò sọ mi di ìríra.

32. “Nítorí Òun kì í ṣe ènìyàn bí èmi,tí èmi ó fi dá a lóhùn tí àwa o fi pàdé ní ìdájọ́.

Ka pipe ipin Jóòbù 9