Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 9:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Jóòbù sì dáhùn ó sì wí pé:

2. “Èmi mọ̀ pe bẹ́ẹ̀ ni ní òtítọ́!Báwo ní ènìyàn yóò ha ti ṣe jẹ́ aláre níwájú Ọlọ́run?

3. Bí ó bá ṣe pé yóò bá jà,òun kì yóò lè dálóhùn kan nínú ẹgbẹ̀rùn-ún ọ̀rọ̀.

4. Ọlọ́gbọ́n nínú àwọn alágbára ní ipa ní Òún;ta ni ó ṣe agídí sí i tí ó sì gbé fún rí?

5. Ẹni tí ó sí òkè nídìí tí wọn kò sì mọ́:tí ó taari wọn ṣubú ní ìbínú rẹ̀

6. Tí ó mi ilẹ̀ ayé tìtì kúrò ní ipò rẹ̀,ọwọ̀n rẹ̀ sì mì tìtì

Ka pipe ipin Jóòbù 9