1. Jóòbù sì dáhùn ó sì wí pé:
2. “Èmi mọ̀ pe bẹ́ẹ̀ ni ní òtítọ́!Báwo ní ènìyàn yóò ha ti ṣe jẹ́ aláre níwájú Ọlọ́run?
3. Bí ó bá ṣe pé yóò bá jà,òun kì yóò lè dálóhùn kan nínú ẹgbẹ̀rùn-ún ọ̀rọ̀.
4. Ọlọ́gbọ́n nínú àwọn alágbára ní ipa ní Òún;ta ni ó ṣe agídí sí i tí ó sì gbé fún rí?
5. Ẹni tí ó sí òkè nídìí tí wọn kò sì mọ́:tí ó taari wọn ṣubú ní ìbínú rẹ̀
6. Tí ó mi ilẹ̀ ayé tìtì kúrò ní ipò rẹ̀,ọwọ̀n rẹ̀ sì mì tìtì
7. Ó pàṣẹ fún oòrùn kò sì le è rànkí ó sì dí ìmọ́lẹ̀ ìràwọ̀ mọ́.
8. Òun nìkanṣoṣo ni ó na ojú ọ̀run lọ,ti ó sì ń rìn lórí ìgbì òkun.
9. Ẹni tí ó dá ìràwọ̀ Béárì, Óríónìàti Píléíádè àti yàrá púpọ̀ ti gúsù.
10. Ẹni tí ń ṣe ohun tí ó tóbi jù àwàrí lọ,àní ohun ìyanu láìní iye.
11. Kíyèsí i, ó ń kọjá lọ ní ẹ̀bá ọ̀dọ̀ mi,èmi kò sì rí i, ó sì kọjá síwáju,bẹ́ẹ̀ ni èmi kò rí ojú rẹ̀.
12. Kiyèsí i, ó já a gbà lọ, ta ni ó lè fà á padà?Ta ni yóò bi í pé kí ni ìwọ ń ṣe nì?