Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 8:8-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. “Èmi bẹ̀ ọ́ ǹjẹ́, bèèrè lọ́wọ́ àwọn ará ìgbà nìkí o sì kíyèsí ìwádìí àwọn baba wọn.

9. Nítorí pé ọmọ-àná ni àwa, a kò sì mọ nǹkan,nítorí pé òjìji ni ọjọ́ wa ni ayé.

10. Àwọn kì yóò wa kọ ọ́, wọn kì yóò sì sọ fún ọ?Wọn kì yóò sì sọ̀rọ̀ láti inú òye wọn jáde wá?

11. Koríko odò ha lè dàgbà láìní ẹrẹ̀tàbí èèsú ha lè dàgbà láìlómi?

12. Nígbà tí ó wà ní tútù, tí a kò kee lulẹ̀,ó rọ dànù, ewéko mìíràn gbogbo hù dípò rẹ̀

13. Bẹ́ẹ̀ ni ipa ọ̀nà gbogbo àwọn tí ó gbàgbé Ọlọ́run,àbá àwọn àgàbàgebè yóò di òfo.

14. Àbá ẹni tí a ó ké kúrò,àti ìgbẹ́kẹ̀lé ẹni tí ó dà bí ilé aláǹtakùn.

15. Yóò fi ara ti ilé rẹ̀, ṣùgbọ́n kì yóò lè dúró,yóò fi di ara rẹ̀ mú ṣinṣin ṣùgbọ́n kì yóò lè dúró pẹ́

16. Ó tutù bí irúgbìn tí a bomirin níwájú òòrùn,ẹ̀ka rẹ̀ sì yọ jáde nínú ọgbà rẹ̀.

17. Gbòǹgbò rẹ̀ ta yí ebè ká,ó sì wó ibi òkúta wọ̀n-ọn-nì.

Ka pipe ipin Jóòbù 8