Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 8:14-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Àbá ẹni tí a ó ké kúrò,àti ìgbẹ́kẹ̀lé ẹni tí ó dà bí ilé aláǹtakùn.

15. Yóò fi ara ti ilé rẹ̀, ṣùgbọ́n kì yóò lè dúró,yóò fi di ara rẹ̀ mú ṣinṣin ṣùgbọ́n kì yóò lè dúró pẹ́

16. Ó tutù bí irúgbìn tí a bomirin níwájú òòrùn,ẹ̀ka rẹ̀ sì yọ jáde nínú ọgbà rẹ̀.

17. Gbòǹgbò rẹ̀ ta yí ebè ká,ó sì wó ibi òkúta wọ̀n-ọn-nì.

18. Bí ó bá sì pa á run kúrò ní ipò rẹ̀,nígbà náà ni ipò náà sẹ́ ẹ pé, ‘Èmi kò ri ọ rí!’

19. Kíyèsí i, ayé rẹ̀ gbẹ dànùàti lati inú ilẹ̀ ní irúgbìn òmìíràn yóò hù jáde wá.

20. “Kíyèsí i, Ọlọ́run kì yóò ta ẹni òtítọ́ nù,bẹ́ẹ̀ ni kì yóò ran oníwà-búburú lọ́wọ́

21. títí yóò fi fi ẹ̀rín kún ọ ní ẹnu,àti ètè rẹ pẹ̀lú ìhó ayọ̀

Ka pipe ipin Jóòbù 8