Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 8:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ígbà náà ni Bílídádì, ará Ṣúà, sì dáhùn wí pé:

2. “Ìwọ yóò ti máa sọ nǹkán wọ̀nyí pẹ́ tó?Tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ yóò sì máa bí ẹ̀fúùfú ńlá?

3. Ọlọ́run a ha máa yí ìdájọ́ po bí,tàbí Olódùmárè a máa fi òtítọ́ sẹ̀ bí?

4. Nígbà tí àwọn ọmọ rẹ̀ sẹ̀ sí i,ó sì gbá wọn kúrò nítorí àṣẹ wọn.

5. Bí ìwọ bá sì képe Ọlọ́run ní ìgbà àkókò,tí ìwọ sì gbàdúrà ẹ̀bẹ̀ sí Olódùmáarè.

6. Ìwọ ìbá mọ́, kí ó sì dúró sinṣsin:ǹjẹ́ nítòótọ́ nísinsìn yìí òun yóò tají fún ọ,òun a sì sọ ibùjókòó òdodo rẹ di púpọ̀.

7. Ìpilẹsẹ̀ rẹ ìbá tilẹ̀ kéré si í,bẹ́ẹ̀ ìgbẹ̀yin rẹ ìbá pọ̀ sí i gidigidi.

8. “Èmi bẹ̀ ọ́ ǹjẹ́, bèèrè lọ́wọ́ àwọn ará ìgbà nìkí o sì kíyèsí ìwádìí àwọn baba wọn.

9. Nítorí pé ọmọ-àná ni àwa, a kò sì mọ nǹkan,nítorí pé òjìji ni ọjọ́ wa ni ayé.

Ka pipe ipin Jóòbù 8