Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 6:9-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Àní Ọlọ́rin ìbá jẹ́ pa mí run,tí òun ì bá jẹ́ siwọ́ rẹ̀ kì ó sì ké mi kúrò.

10. Nígbà náà ní èmi ì bá ní ìtùnú síbẹ̀,àní èmi ì bá mú ọkàn mi le nínú ìbànújẹ́ mi ti kò dá ni sí:nítorí èmi kò fi ọ̀rọ̀ ẹni mímọ́ ni sin rí.

11. “Kí ní agbára mi tí èmi ó fi retí?Kí sì ní òpin mi tí èmi ó fi ní sùúrù?

12. Agbára mi iṣe agbára òkúta bí,tàbí ẹran ara iṣe idẹ?

13. Ìrànlọ́wọ́ mi kò ha wà nínú mi:ọgbọ́n ha ti sálọ kúrò lọ́dọ̀ mi bí?

14. “Ẹni tí àyà rẹ̀ yọ́ dànù, ta ni a bá máa ṣàánú fún láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ rẹ̀ wá,kí ó má ba à kọ ìbẹ̀rù Olódumáarè sílẹ̀?

15. Àwọn ará mi ṣọ̀tẹ̀ bí odò sólobí ìṣàn gúru omi odò sólo, wọ́n ṣàn kọjá lọ.

16. Tí ó dúdú nítorí omi dídì,àti níbi tí odò dídì gbé lùmọ̀ sí.

17. Nígbà kúgbà tí wọ́n bá gbóná wọn a sì yọ́ ṣànlọ,nígbà tí òòrùn bá mú, wọn a sì gbẹ kúrò ni ipò wọn.

18. Ìyà ọ̀nà wọn a sì yípadà sí apá kan,wọ́n gòkè sí ibi asán, wọ́n sì run.

19. Ẹgbẹ́ ogun Témà ń wòyeàwọn ọwọ́ àrò Sébà ń dúró dè wọ́n.

20. Wọ́n já lulẹ̀, nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ wọn lée;wọ́n débẹ̀, wọ́n sì dààmú.

21. Ǹjẹ́ nísinsìn yìí, ẹ̀yin dàbí wọn;ẹ̀yin rí ìrẹ̀sílẹ̀ mi àyà sì fò mí.

22. Èmi ó ha wí pé, ‘Ẹ mú ohun fún mi wá,tàbí pé ẹ fún mi ní ẹ̀bùn nínú ohun ìní yín?

23. Tàbí, ẹgbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá ni,tàbí, ẹrà mí padà kúrò lọ́wọ́ alágbára nì.’?

24. “Ẹ kọ́ mi, èmi ó sì pa ẹnu mi mọ́kí ẹ sì mú mi wòye níbi tí mo gbé ti sìnà.

25. Wò ó! Bí ọ̀rọ̀ òtítọ́ ti lágbára tóṣùgbọ́n kí ni àròyé ìbàwí yín já sí?

26. Ẹ̀yin ṣè bí ẹ ó bá ọ̀rọ̀àti ohùn ẹnu tí ó takú wí tí ó dà bí afẹ́fẹ́.

27. Àní ẹ̀yin ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìní baba,ẹ̀yin sì da iye lé ọ̀rẹ́ yín.

28. “Nítorí náà, kí èyí kí ó tó fún yín.Ẹ má wò mi! Nitorí pé ó hàn gbangba pé:Ní ojú yín ni èmi kì yóò sèké.

Ka pipe ipin Jóòbù 6