8. “Áà! èmi ìbá lè rí ìbéèrè mi gbà;àti pé, kí Ọlọ́run lè fi ohun tí èmi ṣàfẹ́rí fún mi.
9. Àní Ọlọ́rin ìbá jẹ́ pa mí run,tí òun ì bá jẹ́ siwọ́ rẹ̀ kì ó sì ké mi kúrò.
10. Nígbà náà ní èmi ì bá ní ìtùnú síbẹ̀,àní èmi ì bá mú ọkàn mi le nínú ìbànújẹ́ mi ti kò dá ni sí:nítorí èmi kò fi ọ̀rọ̀ ẹni mímọ́ ni sin rí.
11. “Kí ní agbára mi tí èmi ó fi retí?Kí sì ní òpin mi tí èmi ó fi ní sùúrù?
12. Agbára mi iṣe agbára òkúta bí,tàbí ẹran ara iṣe idẹ?
13. Ìrànlọ́wọ́ mi kò ha wà nínú mi:ọgbọ́n ha ti sálọ kúrò lọ́dọ̀ mi bí?
14. “Ẹni tí àyà rẹ̀ yọ́ dànù, ta ni a bá máa ṣàánú fún láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ rẹ̀ wá,kí ó má ba à kọ ìbẹ̀rù Olódumáarè sílẹ̀?
15. Àwọn ará mi ṣọ̀tẹ̀ bí odò sólobí ìṣàn gúru omi odò sólo, wọ́n ṣàn kọjá lọ.
16. Tí ó dúdú nítorí omi dídì,àti níbi tí odò dídì gbé lùmọ̀ sí.
17. Nígbà kúgbà tí wọ́n bá gbóná wọn a sì yọ́ ṣànlọ,nígbà tí òòrùn bá mú, wọn a sì gbẹ kúrò ni ipò wọn.
18. Ìyà ọ̀nà wọn a sì yípadà sí apá kan,wọ́n gòkè sí ibi asán, wọ́n sì run.
19. Ẹgbẹ́ ogun Témà ń wòyeàwọn ọwọ́ àrò Sébà ń dúró dè wọ́n.
20. Wọ́n já lulẹ̀, nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ wọn lée;wọ́n débẹ̀, wọ́n sì dààmú.