1. Jóòbù sì dáhùn ó si wí pé:
2. “Áà! à bá lè wọ̀n ìbìnújẹ́ mi nínú òṣùwọ̀n,kí a sì le gbé ọ̀fọ̀ mi lé orí òṣùwọ̀n ṣọ̀kan pọ̀!
3. Ǹjẹ́ nísinsìn yìí, ìbá wúwo jú iyánrìn òkun lọ:nítorí náà ni ọ̀rọ̀ mi ṣe ń tàsé
4. Nítorí pé ọfà Olódùmárè wọ̀ mi nínú,oró èyí tí ọkàn mi mú;ìpayà-ẹ̀rù Ọlọ́run dúró tì mí.
5. Ǹjẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ìgbẹ́ á máa dún nígbà tí ó bá ní koríko,tàbí ọ̀dá-màlúù a máa dún sórí ìjẹ rẹ̀?
6. A ha lè jẹ ohun tí kò ní adùn ní àìní iyọ̀,tàbi adùn ha wà nínú fúnfún eyin?
7. Ohun ti ọ̀kan mi kọ̀ láti tọ́wò,òun ni ó dàbí oúnjẹ mi tí kò ní adùn.
8. “Áà! èmi ìbá lè rí ìbéèrè mi gbà;àti pé, kí Ọlọ́run lè fi ohun tí èmi ṣàfẹ́rí fún mi.
9. Àní Ọlọ́rin ìbá jẹ́ pa mí run,tí òun ì bá jẹ́ siwọ́ rẹ̀ kì ó sì ké mi kúrò.
10. Nígbà náà ní èmi ì bá ní ìtùnú síbẹ̀,àní èmi ì bá mú ọkàn mi le nínú ìbànújẹ́ mi ti kò dá ni sí:nítorí èmi kò fi ọ̀rọ̀ ẹni mímọ́ ni sin rí.