Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 5:24-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. Ìwọ ó sì mọ̀ pé àlàáfíà ni ibùjókòó rẹ wàìwọ yóò sì máa ṣe ìbẹ̀wò ibùjókòó rẹ, ìwọ kì yóò sìnà.

25. Ìwọ ó sì mọ̀ pẹ̀lú pé irú ọmọ rẹ ó sì pọ̀àti àwọn ọmọ ọmọ rẹ yóò rí bí koríko ìgbẹ́.

26. Ìwọ yóò wọ iṣà òkú rẹ ní ògbólógbòó ọjọ́,bí àpò-ọkà tí ó gbó tí á sì kó ní ìgbà ìkórè rẹ̀.

27. “Kíyèsí i, àwa ti wádìí rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ní ó rí!Gbà á gbọ́, kí o sì mọ̀ pé fún ire ara rẹ ni.”

Ka pipe ipin Jóòbù 5