Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 5:15-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Ṣùgbọ́n ó gba talákà là ní ọwọ́ idà,lọ́wọ́ ẹnu wọn àti lọ́wọ́ àwọn alágbára.

16. Bẹ́ẹ̀ ni ìrètí wà fún talákààìsòótọ́ sì pa ẹnu rẹ̀ mọ́.

17. “Kíyèsíi, ìbùkún ni fún ẹni tí Ọlọ́run bá wí,nítorí náà, má ṣe gan ìbàwí Olódùmarè.

18. Nítorí pé òun a mú ni lára kan,a sì di ìdì ìtura, ó ṣá lọ́gbẹ́, ọwọ́ rẹ̀ á sì mú jìnnà.

19. Yóò gbà ọ́ nínú ìpọ́njú mẹ́fà,àní nínú méje, ibi kan kì yóò bá ọ

20. Nínu ìyànu yóò gbà ọ́ lọ́wọ́ ikúàti nínú ogun, yóò gbà ọ́ lọ́wọ́ idà.

Ka pipe ipin Jóòbù 5