Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 42:8-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Nítorí náà, ẹ mú akọ ẹgbọ̀rọ̀ màlúù méje, àti àgbò méje, kí ẹ sì tọ̀ Jóòbù ìránṣẹ́ mi lọ, kí ẹ sì fi rú ẹbọ sísun fún ara yín; Jóòbù ìránṣẹ́ mi yóò sì gbàdúrà fún yin; nítorí pé àdúrà rẹ̀ ní èmi yóò gbà; kí èmi kí ó má ba ṣe si yín bí ìsìnà yín, níti pé ẹ̀yin kò sọ̀rọ̀ ohun tí ó tọ́ sí mi bi Jóòbù ìránṣẹ́ mi ti ṣe.

9. Bẹ́ẹ̀ ní Élífásì, ara Tẹ́mà, àti Bílídádì, ará Ṣúà, àti Sófárì, ará Námà lọ, wọ́n sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pẹ̀ṣẹ fún wọn. Olúwa sì gba àdúrà Jóòbù.

10. Olúwa sì yí ìgbèkùn Jóòbù padà, nígbà tí ó gbàdúrà fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀; Olúwa sì bù sí ohun gbogbo ti Jóòbù ní rí ní ìṣẹ́po méjì ohun tí ó ní tẹ́lẹ̀ rí

11. Nigbà náà ní gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀, àti gbogbo àwọn arábìnrin rẹ̀, àti gbogbo àwọn tí ó ti ṣe ojúlùmọ̀ rẹ̀ rí; wọ́n báa jẹun nínú ilé rẹ̀. Wọ́n sì ṣe ìdárò rẹ̀, wọ́n sì sìpẹ̀ fún un nítorí ibi gbogbo tí Olúwa ti mú bá a: Olúkúlùkù ènìyàn pẹ̀lú sì fún un ní ẹyọ owo kọ̀ọ̀kan àti olúkúlùkù ni òrùka wúrà etí kọ̀ọ̀kan.

12. Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa bùkún ìgbẹ̀yìn Jóòbù ju ìsáá jú rẹ̀ lọ; ẹgbàá-méje àgùntàn, ẹgbàá-mẹ́ta ràkùnmí, àti ẹgbẹ̀rún àjàgà ọdá-màlúù, àti ẹgbẹ̀rún abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.

13. Ó sì ní ọmọkùnrin méje àti ọmọbìnrin mẹ́ta.

14. Ó sì sọ orúkọ àkọ̀bí ní Jẹ́mímà, àti orúkọ èkejì ni Késíà àti orúkọ ẹ̀kẹta ní Kérén-hápúkì.

15. Àti ní gbogbo ilẹ̀ náà, a kò rí obìnrin tí ó ní ẹwà bí ọmọ Jóòbù; baba wọ́n sì pínlẹ̀ fún wọn ninú àwọn arákùnrin wọn.

16. Lẹ́yìn èyí Jóòbù wà ní ayé ní ogóje ọdún, ó sì rí àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin àti ọmọ-ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, àní ìran mẹ́rin.

17. Bẹ́ẹ̀ ni Jóòbù kú, ó gbó, ó sì kún fún ọjọ́ púpọ̀

Ka pipe ipin Jóòbù 42