Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 42:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ígbà náà ní Jóòbù dá Olúwa lóhùn, ó sì wí pé:

2. “Èmi mọ̀ pé, ìwọ lè e ṣe ohungbogbo, àti pé, kò si ìro inú tí a lè fa sẹ́yìn kurò lọ́dọ̀ rẹ.

3. Ìwọ béèrè, ta ni ẹni tí ń fi ìgbìmọ̀ pamọ́ làíní ìmọ̀?Nítorí náà ní èmi ṣe ń sọ èyití èmi kò mọ̀, ohun tí ó ṣe ìyànu jọjọ níwájú mi, ti èmi kò mòye.

4. “Ìwọ wí pé, ‘gbọ́ tèmi báyìí,èmi ó sì sọ; èmi óbèèrè lọ́wọ́ rẹ, ìwọ yóò sì dá mi lóhùn.’

5. Etí mi sì ti gbọ́ nípa rẹ, ṣùgbọ́nnísinsìnyí ojú mi ti rí ọ.

6. Ǹjẹ́ nítorí náà èmi kórìíra ara mi,mo sì ronúpìwàdà nínú ekuru àti eérú.”

Ka pipe ipin Jóòbù 42