Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 41:3-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Òun ha jẹ́ bẹ ẹ̀bẹ̀ fún àánú lọ́dọ̀rẹ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ bí òun ha bá ọ sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́?

4. Òun ha bá ọ dá májẹ̀mú bí? Ìwọ óha máa mú ṣe ẹrú láéláé bí?

5. Ìwọ hà lè ba saré bí ẹni pé ẹyẹ ni,tàbí ìwọ ó dè é fún àwọn ọmọbìnrin ìránṣẹ́ rẹ̀?

6. Ẹgbẹ́ àwọn apẹja yóò ha máa tà ábí? Wọn ó ha pín láàrin àwọn oníṣòwò?

7. Ìwọ ha lè fi ọ̀kọ̀-irin awọ rẹ̀,tàbí orí rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀kọ̀ ipẹja.

8. Fi ọwọ́ rẹ lée lára, ìwọ ó rántí ìjànáà, ìwọ kì yóò sì ṣe bẹ̀ẹ́ mọ́.

9. Kiyèsí àbá nípaṣẹ̀ rẹ ní asán; níkìkì ìrí rẹ̀ ara kì yóò ha rọ̀ ọ́ wẹ̀sì?

10. Kò sí ẹni aláyà lílé tí ó lè rusókè; Ǹjẹ́ ta ni ó lè dúró níwájú mi.

11. Ta ni ó ṣáájú ṣe fún mi, tí èmi ìbáfi san-án fún un? Ohunkóhun ti ń bẹ lábẹ́ ọ̀run gbogbo, tèmi ni.

12. “Èmi kì yóò fi ẹ̀yà ara rẹ, tàbi ipárẹ, tàbí ìhámọ́ra rẹ tí ó ní ẹwà pamọ́.

13. Ta ni yóò lè rídìí aṣọ àpáta rẹ?Tàbí ta ni ó lè súnmọ́ ọ̀nà méjì ẹ̀yìn rẹ.?

14. Ta ni ó lè sí ìlẹ̀kùn ẹnu rẹ?Àyíká ẹ̀yin rẹ ni ìbẹ̀rù ńlá.

Ka pipe ipin Jóòbù 41