Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 41:26-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

26. Ọ̀kọ̀ tàbí idà, tàbi ọfà, ẹni tí ó sáa kò lè rán an.

27. Ó ká ìrin sí bi koríko gbígbẹ àtiidẹ si bi igi híhù.

28. Ọfà kò lè mú un sá; òkútakànnakánná lọ́dọ̀ rẹ̀ dàbí àkékù koríko.

29. Ó ka ẹṣin sí bí àkékù idi koríko;ó rẹ́rin-ín sí mímì ọ̀kọ̀.

30. Òkúta mímú ń bẹ nísàlẹ̀ abẹ́ rẹ̀, ósì tẹ́ ohun mímú ṣónṣó sórí ẹrẹ̀.

31. Ó mú ibú omi hó bí ìkòkò; ó sọ̀agbami òkun dàbí kólòbó ìkunra.

32. Ó mú ipa ọ̀nà tan lẹ́yìn rẹ̀; ènìyàna máa ka ibú sí ewú arúgbó.

33. Lórí ilẹ̀ ayé kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ̀,tí a dá láìní ìbẹ̀rù.

34. Ó bojú wo ohun gíga gbogbo, ósì nìkan já sí ọba lórí gbogboàwọn ọmọ ìgbéraga.”

Ka pipe ipin Jóòbù 41