22. Ní ọrún rẹ̀ ní agbára kù sí, àtiìbànújẹ́ àyà sì padà di ayọ̀ níwájú rẹ̀.
23. Jabajaba ẹran rẹ̀ dìjọ pọ̀, wọ́nmúra gírí fún ara wọn, a kò lè sí wọn nípò.
24. Àyà rẹ̀ dúró gbagigbagi bí òkúta,àní ó le bi ìyá ọlọ.
25. Nígbà tí ó bá gbé ara rẹ̀ sókè,àwọn alágbára bẹ̀rù; nítoríìbẹ̀rù ńlá, wọ́n dààmú.
26. Ọ̀kọ̀ tàbí idà, tàbi ọfà, ẹni tí ó sáa kò lè rán an.
27. Ó ká ìrin sí bi koríko gbígbẹ àtiidẹ si bi igi híhù.
28. Ọfà kò lè mú un sá; òkútakànnakánná lọ́dọ̀ rẹ̀ dàbí àkékù koríko.