Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 41:16-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Èkíní fi ara mọ́ èkejì tóbẹ́ẹ̀ tí afẹ́fẹ́kò lè wọ àárin wọn.

17. Èkíní fi ara mọ́ èkejì rẹ̀; wọ́n lẹ̀wọ́n pọ̀ tí a kò lè mọ̀ wọ́n.

18. Nípa sísin rẹ̀ ìmọ́lẹ̀ mọ́, ojú rẹ̀ asì dàbí ìpénpéjú òwúrọ̀.

19. Láti ẹnu rẹ ni ọ̀wọ́ iná ti jádewá, ìpẹ́pẹ́ iná a sì ta jáde.

20. Láti imu rẹ ni èéfín ti jáde wá,bí ẹni pé láti inú ìkòkò tí a fẹ́ iná ìféfé lábẹ́ rẹ̀.

21. Èémi rẹ̀ tinábọ ẹ̀yin, ọ̀wọ́ iná sìti ẹnu rẹ̀ jáde.

22. Ní ọrún rẹ̀ ní agbára kù sí, àtiìbànújẹ́ àyà sì padà di ayọ̀ níwájú rẹ̀.

23. Jabajaba ẹran rẹ̀ dìjọ pọ̀, wọ́nmúra gírí fún ara wọn, a kò lè sí wọn nípò.

24. Àyà rẹ̀ dúró gbagigbagi bí òkúta,àní ó le bi ìyá ọlọ.

Ka pipe ipin Jóòbù 41