Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 41:14-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Ta ni ó lè sí ìlẹ̀kùn ẹnu rẹ?Àyíká ẹ̀yin rẹ ni ìbẹ̀rù ńlá.

15. Ipẹ́ lílé ní ìgbéraga rẹ̀; ó pàdépọ̀ tímọ́tímọ́ bí àmì èdìdì.

16. Èkíní fi ara mọ́ èkejì tóbẹ́ẹ̀ tí afẹ́fẹ́kò lè wọ àárin wọn.

17. Èkíní fi ara mọ́ èkejì rẹ̀; wọ́n lẹ̀wọ́n pọ̀ tí a kò lè mọ̀ wọ́n.

18. Nípa sísin rẹ̀ ìmọ́lẹ̀ mọ́, ojú rẹ̀ asì dàbí ìpénpéjú òwúrọ̀.

19. Láti ẹnu rẹ ni ọ̀wọ́ iná ti jádewá, ìpẹ́pẹ́ iná a sì ta jáde.

20. Láti imu rẹ ni èéfín ti jáde wá,bí ẹni pé láti inú ìkòkò tí a fẹ́ iná ìféfé lábẹ́ rẹ̀.

Ka pipe ipin Jóòbù 41