Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 41:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Ǹjẹ́ ìwọ lè ífi ìwọ fa Lefíátanì,ọ̀nì ńlá jáde? Tàbí ìwọ lè fi okùn so ahọ́n rẹ̀ mọ́lẹ̀?

2. Ìwọ lè fi okùn bọ̀ ọ́ ní ímú,tàbí fi ìwọ̀ gun ní ẹ̀rẹ̀kẹ́?

3. Òun ha jẹ́ bẹ ẹ̀bẹ̀ fún àánú lọ́dọ̀rẹ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ bí òun ha bá ọ sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́?

4. Òun ha bá ọ dá májẹ̀mú bí? Ìwọ óha máa mú ṣe ẹrú láéláé bí?

5. Ìwọ hà lè ba saré bí ẹni pé ẹyẹ ni,tàbí ìwọ ó dè é fún àwọn ọmọbìnrin ìránṣẹ́ rẹ̀?

6. Ẹgbẹ́ àwọn apẹja yóò ha máa tà ábí? Wọn ó ha pín láàrin àwọn oníṣòwò?

7. Ìwọ ha lè fi ọ̀kọ̀-irin awọ rẹ̀,tàbí orí rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀kọ̀ ipẹja.

8. Fi ọwọ́ rẹ lée lára, ìwọ ó rántí ìjànáà, ìwọ kì yóò sì ṣe bẹ̀ẹ́ mọ́.

9. Kiyèsí àbá nípaṣẹ̀ rẹ ní asán; níkìkì ìrí rẹ̀ ara kì yóò ha rọ̀ ọ́ wẹ̀sì?

10. Kò sí ẹni aláyà lílé tí ó lè rusókè; Ǹjẹ́ ta ni ó lè dúró níwájú mi.

11. Ta ni ó ṣáájú ṣe fún mi, tí èmi ìbáfi san-án fún un? Ohunkóhun ti ń bẹ lábẹ́ ọ̀run gbogbo, tèmi ni.

12. “Èmi kì yóò fi ẹ̀yà ara rẹ, tàbi ipárẹ, tàbí ìhámọ́ra rẹ tí ó ní ẹwà pamọ́.

13. Ta ni yóò lè rídìí aṣọ àpáta rẹ?Tàbí ta ni ó lè súnmọ́ ọ̀nà méjì ẹ̀yìn rẹ.?

14. Ta ni ó lè sí ìlẹ̀kùn ẹnu rẹ?Àyíká ẹ̀yin rẹ ni ìbẹ̀rù ńlá.

Ka pipe ipin Jóòbù 41