Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 40:15-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. “Ǹjẹ́ nísinsìnyí kíyèsí Béhámótì tímo dá pẹ̀lú rẹ: òun ha máa jẹ koríko bí ọ̀dá màlúù.

16. Wò o nísinsìnyí, agbára rẹ wà níẹ̀gbẹ́ rẹ, àti ipa rẹ nínú ìṣàn ìkún rẹ.

17. Òun a máa jù ìru rẹ̀ bí i igikédarì; Isan itan rẹ̀ dijọ pọ̀.

18. Egungun rẹ̀ ní ògùsọ̀ idẹ;Egungun rẹ̀ dàbí ọ̀pá irin.

19. Òun ni olórí nínú àwọn iṣẹ́Ọlọ́run; ṣíbẹ̀ Ẹlẹ́dàá rẹ̀ fi idà rẹ̀ lé e lọ́wọ́.

20. Nítòótọ́ òkè ńláńlá ní imu ohunjíjẹ fún un wá, níbi tí gbogboẹranko ìgbẹ́ máa siré ní ẹ̀gbẹ́ ibẹ̀

21. Ó dùbúlẹ̀ lábẹ́ igi lótósì,lábẹ́ èèsún àti ẹrẹ̀.

Ka pipe ipin Jóòbù 40