Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 37:7-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Ó fi èdìdì di ọwọ́ gbogbo ènìyàn kígbogbo wọn kí ó lè mọ iṣẹ́ rẹ̀ó sì tún dá olúkúlùkù ẹ̀nìyàn dúró lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀

8. Nígbà náà ní àwọn ẹranko wọ inúihò lọ, wọn a sì wà ni ipò wọn.

9. Láti ìhà gúsù ni ìjì àjàyíká tí jádewá, àti òtútù láti inú afẹ́fẹ́ ti tú àwọ̀sánmọ̀ ká.

10. Nípa ẹ̀mí Ọlọ́run a fí ìdí-omi fúnni, ibú-omi á sì sún kì.

11. Pẹ̀lúpẹ̀lú ó fi omi púpọ̀ múàwọ̀sánmọ̀ wúwo, a sì túàwọ̀sánmọ̀ ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ká ara wọn.

12. Àwọn wọ̀nyí i káàriri nípà ìlànàrẹ̀, kí wọn kí ó lé ṣe ohunkohuntí ó pa láṣẹ fún wọn lórí ilẹ̀ ayé.

Ka pipe ipin Jóòbù 37