Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 37:5-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Ọlọ́run fi ohùn rẹ̀ sán àrá níọ̀nà ìyanu; ohùn ńláńlá ni íṣe tí àwa kò le mọ̀.

6. Nítori tí ó wí fún Sínóó pé, Ìwọ rọ̀sílẹ̀ ayé, àti pẹ̀lú fún ọwọ́ òjò, àti fún òjò ńlá agbára rẹ̀.

7. Ó fi èdìdì di ọwọ́ gbogbo ènìyàn kígbogbo wọn kí ó lè mọ iṣẹ́ rẹ̀ó sì tún dá olúkúlùkù ẹ̀nìyàn dúró lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀

8. Nígbà náà ní àwọn ẹranko wọ inúihò lọ, wọn a sì wà ni ipò wọn.

9. Láti ìhà gúsù ni ìjì àjàyíká tí jádewá, àti òtútù láti inú afẹ́fẹ́ ti tú àwọ̀sánmọ̀ ká.

10. Nípa ẹ̀mí Ọlọ́run a fí ìdí-omi fúnni, ibú-omi á sì sún kì.

11. Pẹ̀lúpẹ̀lú ó fi omi púpọ̀ múàwọ̀sánmọ̀ wúwo, a sì túàwọ̀sánmọ̀ ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ká ara wọn.

12. Àwọn wọ̀nyí i káàriri nípà ìlànàrẹ̀, kí wọn kí ó lé ṣe ohunkohuntí ó pa láṣẹ fún wọn lórí ilẹ̀ ayé.

13. Ó mú àwọ̀sánmọ̀ wá, ìbá ṣẹ fúnìkìlọ̀, tàbí omi wá sí ayé láti fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn.

14. “Jóòbù, dẹtí sílẹ̀ sí èyí; dúró jẹ́ẹ́ kío sì ro iṣẹ́ ìyanu Ọlọ́run.

15. Ìwọ mọ àkókò ìgbà tí Ọlọ́run sọwọ́n lọ́jọ̀, tí ó sì mú ìmọ́lẹ̀ àwọ̀sánmọ̀ rẹ̀ dán?

16. Ìwọ mọ ti àwọ̀sánmọ̀ í fòó lọ,iṣẹ́ ìyanu ẹni tí ó pé ní ìmọ̀?

Ka pipe ipin Jóòbù 37