Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 37:16-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Ìwọ mọ ti àwọ̀sánmọ̀ í fòó lọ,iṣẹ́ ìyanu ẹni tí ó pé ní ìmọ̀?

17. Aṣọ rẹ̀ ti máa gbóná, nígbà tí ó fiatẹ́gùn ìhà gúsù mú ayé dákẹ́.

18. Ìwọ ha ba tẹ́ pẹpẹ ojú ọ̀run, tí ódúró sinsin, tí ó sì dàbí dígi tí ó yọ̀ dà?

19. “Kọ́ wa ní èyí tí a lè wí fún un;nítorí pé àwa kò le ílàdí ọ̀rọ̀ nítorí òkùnkùn wa.

20. A ó ha wí fún un pé, èmi fẹ́sọ̀rọ̀? Tàbí ẹnìkan lèwí pé, ìfẹ́ mi ni pé kí a gbémi mù?

21. Ṣibẹ̀ nísinsin yìí ènìyàn kò ríoòrùn tí ń dán nínú àwọ̀sánmọ̀,ṣùgbọ́n afẹ́fẹ́ ń kọjá, a sì fẹ́ wọn mọ́.

22. Góòlù dídán ti inú ìhà àríwá jádewá; lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni ọláńlá ẹ̀rùn ńlá.

23. Nipa ti Olódùmarè àwa kò le wádìí rẹ̀; ó ré kọjá ní ipá; nínúìdájọ́ àtí títí bi oun kì í ba ẹ̀tọ́ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ òtítọ́ jẹ́.

24. Nítorí náà ènìyàn ha máa bẹ̀rùrẹ̀; òun kì í se ojú sájú ẹnikẹ́ni tí ó gbọ́n ní ayé?”

Ka pipe ipin Jóòbù 37