Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 35:9-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. “Nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìninilára, wọ́n múni kígbe; wọ́n kigbe nípa apá àwọn alágbára.

10. Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó wí pé, ‘Níboni Ọlọ́run Ẹlẹ́dàá mi wà tí ó sì fi orin fún mi ní òru;

11. Tí òun kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ jù àwọnẹranko ayé lọ, tí ó sì mú wagbọ́n ju àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run lọ?’

12. Nígbà náà ni wọ́n ń ké ṣùgbọ́nỌlọ́run kò dáhùn nítorí ìgbéraga ènìyàn búburú.

13. Nítòótọ́ Ọlọ́run kì yóò gbọ́ asán;bẹ́ẹ̀ ní Olódùmarè kì yóò kà á sí.

14. Bí ó tilẹ̀ ṣe pé ìwọ wí pé ìwọ kì írí i, ọ̀rọ̀ ìdájọ́, ń bẹ níwájú rẹ,ẹni tí ìwọ sì gbọdọ̀ dúró dè.

15. Ṣùgbọ́n nísinsìnyí nítorí tí ìbínúrẹ̀ kò tí ṣẹ́ ọ níṣẹ̀ẹ́, òun kò ha lèhun ímọ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwà búrubú bí?

16. Nítorí náà ní Jóòbù se ya ẹnu rẹ̀lásán ó ṣọ ọ̀rọ̀ di púpọ̀ láìsí ìmọ̀.”

Ka pipe ipin Jóòbù 35