Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 35:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Elíhù sì wí pe:

2. “Ìwọ rò pé èyí ha tọ́, tí ìwọ wí pé,òdodo mi ni èyí níwájú Ọlọ́run?

3. Nítorí tí ìwọ wí pé èrè kí ní yóòjá sí fún ọ, tàbí èrè kí ni èmi yóò fi jẹ́ ju èrè ẹ̀ṣẹ̀ mi lọ.

4. “Èmi ó dá ọ lóhùn àti àwọn ẹgbẹ́ rẹpẹ̀lú rẹ.

5. Ṣíjú wo ọ̀run; kí o rí i, ki o sìbojúwo àwọ̀sánmọ̀ tí ó ga jù ọ lọ

6. Bí ìwọ bá sẹ̀ kí ni ìwọ fi sẹ̀ sí? Tàbíbí àìṣedéédéé rẹ di púpọ̀, kí ni ìwọ fi èyí nì ṣe sí i?

7. Bí ìwọ bá sì ṣe olódodo, kí ni ìwọfí fún u, tàbí kí ni òun rí gbà láti ọwọ́ rẹ wá?

8. Ìwà búburú rẹ ni fún ènìyàn bíìwọ; òdodo rẹ sì ni fún ọmọ ènìyàn.

9. “Nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìninilára, wọ́n múni kígbe; wọ́n kigbe nípa apá àwọn alágbára.

Ka pipe ipin Jóòbù 35