Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 33:8-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. “Nítòótọ́ ìwọ sọ ní etí mi, èmí sìgbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ wí pé,

9. ‘Èmí mọ́, laini ẹ̀ṣẹ̀ ìrékọjá;Àláìṣẹ̀ ní èmí; bẹ́ẹ̀ àìṣéédéé kò sí ní ọwọ́ mi.

10. Kíyèsí i, Ọlọ́run ti rí àìṣedéédéépẹ̀lú mi; ó kà mí sì ọ̀tá rẹ̀.

11. Ó kàn ẹ̀ṣẹ̀ mi sínú àbà; o kíyèsiipa ọ̀nà mi gbogbo.’

12. “Kíyèsí i, nínú èyí ìwọ sìnà! Èmí odá ọ lóhùn pé, Ọlọ́run tóbi jù ènìyàn lọ!

13. Nítorí kí ni ìwọ ṣe ń báa jà, wí pé,òun kò níi sọ ọ̀rọ̀ kan nítorí iṣẹ́ rẹ̀?

14. Nítorí pe Ọlọ́run sọ̀rọ̀ lẹ́ẹkan, ànílẹ́ẹkẹji, ṣùgbọn ènìyàn kò róye rẹ̀.

15. Nínú àlá, ní ojúran òru, nígbàtó orun ìjìká bá kùn ènìyàn lọ, ní sísùn lórí ìbùṣùn,

16. Nígbà náà ni ó lè sọ̀rọ̀ ní etíwọn, yóò sì dẹ́rùbà wọ́n pẹ̀lú ìbáwí,

17. Kí ó lè fa ènìyàn sẹ́yìn kúrò nínúètè rẹ̀; Kí ó sì pa ìgbéraga mọ́ kúrò lọ́dọ̀ ènìyàn;

18. Ó sì fa ọkàn rẹ̀ pàdà kúro nínúìsà-òkú, àti ẹ̀mí rẹ̀ láti ṣẹ̀gbé lọ́wọ́ ìdà.

19. A sì nà á lórí ibùsùn ìrọra rẹ̀;Pẹ̀lúpẹ̀lú a fi ìjà egungun rẹ̀ ti ó dúró pẹ́ nà án.

20. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀mírẹ kọ ounjẹ, ọkàn rẹ̀ sì kọ oúnjẹ dídùn.

21. Ẹran ara rẹ̀ run, títí a kò sì fi lè ríi mọ́egungun rẹ̀ tí a kò rí sì ta jáde.

22. Àní ọkàn rẹ̀ sì súnmọ́ ìsà òkú,ẹ̀mí rẹ̀ sìsúnmọ́ ọ̀dọ̀ àwọn ìranṣẹ́ ikú.

23. “Bí oníṣẹ́ kan ba wà lọ́dọ̀ rẹ̀, ẹni tíń ṣe alágbàwí, ọ̀kan ninú ẹgbẹ̀rún láti fi ọ̀nà pípé hàn ni,

24. Nígbà náà ni ó ṣe oore ọ̀fẹ́ fún un ó sìwí pé, gbà á kúrò nínú ìlọ sínúìsà òkú èmi ti ràá pàdà;

25. Ara rẹ̀ yóò sì di ọ̀tun bí i ti ọmọkékeré, yóò sì tún padà sí ọjọ́ ìgbà èwe rẹ̀;

Ka pipe ipin Jóòbù 33