Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 33:2-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Kíyèsí i nísinsìnyí, èmí ya ẹnumi, ahọ́n mi sì sọ̀rọ̀ ní ẹnu mi.

3. Ọ̀rọ̀ mi yóò sì jási ìdúró ṣinṣinọkàn mi, ètè mi yóò sì sọ ìmọ̀ mi jáde dájúdájú.

4. Ẹ̀mí Ọlọ́run Ní ó tí dá mi,Àti ìmísí Olódùmáre ni ó ti fún mi ní ìyè.

5. Bí ìwọ bá le dá mi lóhùn,tò ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ṣẹẹsẹ níwájú mi; dìdé!

6. Kíyèsí i, bí ìwọ ṣe jẹ́ ti Ọlọ́run,bẹ́ẹ̀ ni èmí náà; láti amọ̀ wá ni a sì ti dá mi pẹ̀lú

7. Kíyèsí i, ẹrù ń lá mi kì yóò bà ọ;bẹ́ẹ̀ ni ọwọ́ mi kì yóò wúwo sí ọ lára.

8. “Nítòótọ́ ìwọ sọ ní etí mi, èmí sìgbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ wí pé,

9. ‘Èmí mọ́, laini ẹ̀ṣẹ̀ ìrékọjá;Àláìṣẹ̀ ní èmí; bẹ́ẹ̀ àìṣéédéé kò sí ní ọwọ́ mi.

Ka pipe ipin Jóòbù 33